-
Jeremáyà 43:11-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ó máa wọlé, á sì kọ lu ilẹ̀ Íjíbítì.+ Ẹni tó bá yẹ fún àjàkálẹ̀ àrùn ni àjàkálẹ̀ àrùn máa pa, ẹni tó bá yẹ fún oko ẹrú ló máa lọ sí oko ẹrú, ẹni tó bá sì yẹ fún idà ni idà máa pa.+ 12 Màá sọ iná sí ilé* àwọn ọlọ́run Íjíbítì, ọba náà á sun wọ́n,+ á sì kó wọn lọ sí oko ẹrú. Á da ilẹ̀ Íjíbítì bora bí olùṣọ́ àgùntàn ti ń da ẹ̀wù bo ara rẹ̀, á sì jáde kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà.* 13 Á fọ́ àwọn òpó* Bẹti-ṣémẹ́ṣì* tó wà nílẹ̀ Íjíbítì sí wẹ́wẹ́, á sì dáná sun ilé* àwọn ọlọ́run Íjíbítì.”’”
-