ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóẹ́lì 2:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 “Ẹ fun ìwo ní Síónì!+

      Ẹ kéde ogun ní òkè mímọ́ mi.

      Kí jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà,*

      Torí ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀!+ Ó sún mọ́lé!

       2 Ó jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù,+

      Ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà,+

      Bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀ lórí àwọn òkè.

      Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì lágbára;+

      Kò tíì sí irú wọn rí,

      Irú wọn kò sì ní sí mọ́ láé,

      Jálẹ̀ àwọn ọdún láti ìran dé ìran.

  • Sefanáyà 1:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé!+

      Ó sún mọ́lé, ó sì ń yára bọ̀ kánkán!*+

      Ìró ọjọ́ Jèhófà korò.+

      Akíkanjú ológun máa figbe ta níbẹ̀.+

      15 Ọjọ́ yẹn jẹ́ ọjọ́ ìbínú ńlá,+

      Ọjọ́ wàhálà àti ìdààmú,+

      Ọjọ́ ìjì àti ìsọdahoro,

      Ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù,+

      Ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà,+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́