17 Ọlọ́run tòótọ́ fún àwọn ọ̀dọ́* mẹ́rin yìí ní ìmọ̀ àti òye nínú oríṣiríṣi ìkọ̀wé àti ọgbọ́n; ó sì fún Dáníẹ́lì ní òye láti túmọ̀ onírúurú ìran àti àlá.+
20 Nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba bi wọ́n, tó gba ọgbọ́n àti òye, ó rí i pé wọ́n fi ìlọ́po mẹ́wàá dáa ju gbogbo àwọn àlùfáà onídán àti àwọn pidánpidán+ tó wà ní gbogbo ibi tó jọba lé lórí.