-
Ẹ́sítà 3:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Wọ́n wá pe àwọn akọ̀wé ọba+ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìíní. Wọ́n kọ+ gbogbo àṣẹ tí Hámánì pa fún àwọn baálẹ̀ ọba, àwọn gómìnà tó ń ṣàkóso àwọn ìpínlẹ̀* àti àwọn olórí àwùjọ èèyàn lóríṣiríṣi, wọ́n kọ ọ́ sí ìpínlẹ̀* kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà ìgbàkọ̀wé tirẹ̀ àti sí àwùjọ àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn. Wọ́n kọ ọ́ ní orúkọ Ọba Ahasuérúsì, wọ́n sì fi òrùka àṣẹ ọba gbé èdìdì lé e.+
-
-
Ẹ́sítà 8:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ó kọ ọ́ ní orúkọ Ọba Ahasuérúsì, ó fi òrùka àṣẹ ọba+ gbé èdìdì lé e, ó sì fi àwọn ìwé náà rán àwọn asáréjíṣẹ́ tó ń gun ẹṣin; ẹṣin àfijíṣẹ́ tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá nílẹ̀ ni wọ́n gùn, iṣẹ́ ọba sì ni àwọn ẹṣin náà wà fún.
-