-
Ẹ́sítà 1:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Tó bá dáa lójú ọba, kó pa àṣẹ kan, kí wọ́n sì kọ ọ́ sínú àwọn òfin Páṣíà àti Mídíà tí kò ṣeé yí pa dà,+ pé kí Fáṣítì má ṣe wá síwájú Ọba Ahasuérúsì mọ́ láé; kí ọba sì fi ipò ayaba fún obìnrin tó sàn jù ú lọ.
-
-
Ẹ́sítà 8:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ní báyìí, ẹ kọ ohunkóhun tó bá dáa lójú yín lórúkọ ọba nítorí àwọn Júù, kí ẹ sì fi òrùka àṣẹ ọba gbé èdìdì lé e, nítorí ìwé àṣẹ tí wọ́n bá kọ lórúkọ ọba, tí wọ́n sì fi òrùka àṣẹ ọba gbé èdìdì lé kò ṣeé yí pa dà.”+
-