-
Jeremáyà 32:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Wò ó! Agbára ńlá rẹ+ àti apá rẹ tí o nà jáde lo fi dá ọ̀run àti ayé. Kò sí ohun tó ṣòroó ṣe fún ọ, 18 ìwọ Ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, àmọ́ tí ò ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára* àwọn ọmọ tí wọ́n fi sílẹ̀,+ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́, tí o jẹ́ Ẹni ńlá àti alágbára ńlá, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ. 19 Ìpinnu rẹ* ga, àwọn iṣẹ́ rẹ sì tóbi,+ ìwọ tí ojú rẹ ń wo gbogbo ọ̀nà àwọn èèyàn,+ láti san èrè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ṣe.+
-