-
Léfítíkù 26:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 èmi, ní tèmi, yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí sí yín: màá kó ìdààmú bá yín láti fìyà jẹ yín, màá fi ikọ́ ẹ̀gbẹ àti akọ ibà ṣe yín, yóò mú kí ojú yín di bàìbàì, kí ẹ* sì ṣègbé. Lásán ni ẹ máa fún irúgbìn yín, torí àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ ẹ́.+ 17 Mi ò ní fojúure wò yín, àwọn ọ̀tá yín á sì ṣẹ́gun yín;+ àwọn tó kórìíra yín yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀,+ ẹ ó sì sá nígbà tí ẹnì kankan ò lé yín.+
-
-
Diutarónómì 28:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Àmọ́ tí o ò bá pa gbogbo àṣẹ àti òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, láti fi hàn pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀, gbogbo ègún yìí máa wá sórí rẹ, ó sì máa bá ọ:+
-