8 Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Dáníẹ́lì wá síwájú mi, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹtiṣásárì,+ látinú orúkọ ọlọ́run mi,+ ẹni tí ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ + wà nínú rẹ̀, mo sì rọ́ àlá náà fún un:
12 Torí Dáníẹ́lì, ẹni tí ọba pè ní Bẹtiṣásárì,+ ní ẹ̀mí tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye láti túmọ̀ àwọn àlá, láti ṣàlàyé àwọn àlọ́, kó sì wá ojútùú sí ohun tó bá lọ́jú pọ̀.*+ Jẹ́ kí wọ́n pe Dáníẹ́lì wá, ó sì máa sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”