-
Àwọn Onídàájọ́ 19:22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Bí wọ́n ṣe ń gbádùn ara wọn, àwọn ọkùnrin kan tí kò ní láárí nínú ìlú yí ilé náà ká, wọ́n sì ń gbá ilẹ̀kùn, wọ́n ń sọ fún bàbá arúgbó tó ni ilé náà pé: “Mú ọkùnrin tó wá sínú ilé rẹ jáde, ká lè bá a lò pọ̀.”+
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 20:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Ọmọ Léfì,+ tó jẹ́ ọkọ obìnrin tí wọ́n pa náà wá dáhùn pé: “Èmi àti wáhàrì mi wá sun Gíbíà+ ti Bẹ́ńjámínì mọ́jú. 5 Ni àwọn tó ń gbé* Gíbíà bá dìde sí mi, wọ́n sì yí ilé náà ká ní òru. Èmi ni wọ́n fẹ́ pa, àmọ́ dípò ìyẹn, wáhàrì* mi ni wọ́n fipá bá lò pọ̀, ó sì kú.+ 6 Mo wá mú òkú wáhàrì mi, mo gé e sí wẹ́wẹ́, mo sì fi àwọn ègé náà ránṣẹ́ sí gbogbo ilẹ̀ tí Ísírẹ́lì jogún,+ torí ìwà burúkú àti ìwà tó ń dójú tini ni wọ́n hù ní Ísírẹ́lì.
-
-
Hósíà 10:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Láti ìgbà àwọn ará Gíbíà ni o ti ṣẹ̀,+ ìwọ Ísírẹ́lì.
Síbẹ̀, ìwọ kò jáwọ́.
Ogun kò pa àwọn aláìṣòdodo tó wà ní Gíbíà run pátápátá.
-