18 Ní ọdún kẹta Hóṣéà+ ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì, Hẹsikáyà+ ọmọ Áhásì+ ọba Júdà di ọba. 2 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ábì ọmọ Sekaráyà.+ 3 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà+ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+