Ẹ́kísódù 3:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Ọlọ́run wá sọ fún Mósè lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ọlọ́run Ísákì+ àti Ọlọ́run Jékọ́bù+ ló rán mi sí yín.’ Èyí ni orúkọ mi títí láé,+ bí wọ́n á sì ṣe máa rántí mi láti ìran dé ìran nìyí. Émọ́sì 4:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Nítorí, wò ó! Òun ló dá àwọn òkè+ àti afẹ́fẹ́;+Ó ń sọ èrò Rẹ̀ fún àwọn èèyàn,Ó ń sọ ìmọ́lẹ̀ di òkùnkùn,+Ó ń rìn lórí àwọn ibi gíga ayé;+Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.” Émọ́sì 5:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Ẹni tó dá àgbájọ ìràwọ̀ Kímà* àti àgbájọ ìràwọ̀ Késílì,*+Ẹni tó ń sọ òkùnkùn biribiri di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,Ẹni tó ń mú kí ọ̀sán ṣókùnkùn bí òru,+Ẹni tó ń wọ́ omi jọ látinú òkunKí ó lè dà á sórí ilẹ̀,+Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.
15 Ọlọ́run wá sọ fún Mósè lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ọlọ́run Ísákì+ àti Ọlọ́run Jékọ́bù+ ló rán mi sí yín.’ Èyí ni orúkọ mi títí láé,+ bí wọ́n á sì ṣe máa rántí mi láti ìran dé ìran nìyí.
13 Nítorí, wò ó! Òun ló dá àwọn òkè+ àti afẹ́fẹ́;+Ó ń sọ èrò Rẹ̀ fún àwọn èèyàn,Ó ń sọ ìmọ́lẹ̀ di òkùnkùn,+Ó ń rìn lórí àwọn ibi gíga ayé;+Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.”
8 Ẹni tó dá àgbájọ ìràwọ̀ Kímà* àti àgbájọ ìràwọ̀ Késílì,*+Ẹni tó ń sọ òkùnkùn biribiri di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,Ẹni tó ń mú kí ọ̀sán ṣókùnkùn bí òru,+Ẹni tó ń wọ́ omi jọ látinú òkunKí ó lè dà á sórí ilẹ̀,+Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.