25 Ó gba ààlà ilẹ̀ Ísírẹ́lì pa dà láti Lebo-hámátì*+ títí dé Òkun Árábà,*+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ, ìyẹn Jónà+ ọmọ Ámítáì, wòlíì tó wá láti Gati-héférì.+
29 Nígbà tí àwọn èrò ń kóra jọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ìran burúkú ni ìran yìí; ó ń wá àmì, àmọ́ a ò ní fún un ní àmì kankan àfi àmì Jónà.+30 Torí bí Jónà+ ṣe di àmì fún àwọn ará Nínéfè, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ èèyàn ṣe máa jẹ́ fún ìran yìí.