16 Ní ọdún kẹtàdínlógún Pékà ọmọ Remaláyà, Áhásì+ ọmọ Jótámù ọba Júdà di ọba. 2 Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+