ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 25:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Torí náà, mo gba ife náà lọ́wọ́ Jèhófà, mo sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè tí Jèhófà rán mi sí mu ún:+

  • Jeremáyà 25:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 àti onírúurú àjèjì tó wà láàárín wọn, gbogbo ọba ilẹ̀ Úsì, gbogbo ọba ilẹ̀ Filísínì+ àti Áṣíkẹ́lónì+ àti Gásà àti Ẹ́kírónì àti àwọn tó ṣẹ́ kù ní Áṣídódì,

  • Émọ́sì 1:6-8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,

      ‘“Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta ti Gásà+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,

      Nítorí wọ́n kó gbogbo àwọn èèyàn nígbèkùn,+ wọ́n sì fà wọ́n lé Édómù lọ́wọ́.

       7 Torí náà, màá rán iná sí ògiri Gásà,+

      Á sì jó àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò run.

       8 Màá pa àwọn tó ń gbé Áṣídódì run,+

      Àti àwọn tó ń ṣàkóso* ní Áṣíkẹ́lónì;+

      Màá fìyà jẹ Ẹ́kírónì,+

      Àwọn Filísínì tó ṣẹ́ kù yóò sì ṣègbé,”+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’

  • Sekaráyà 9:5, 6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Áṣíkẹ́lónì á rí i, ẹ̀rù á sì bà á;

      Gásà yóò jẹ̀rora,

      Bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹ́kírónì, torí pé ìrètí rẹ̀ ti di ìtìjú.

      Ọba kan yóò ṣègbé ní Gásà,

      Ẹnì kankan kò sì ní gbé ní Áṣíkẹ́lónì.+

       6 Ọmọ àjèjì ni yóò gbé ní Áṣídódì,

      Màá sì fòpin sí ìgbéraga ará Filísínì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́