3 Ó tún àwọn ibi gíga kọ́, èyí tí Hẹsikáyà bàbá rẹ̀ ti wó lulẹ̀,+ ó mọ àwọn pẹpẹ fún Báálì, ó sì ṣe àwọn òpó òrìṣà.* Ó forí balẹ̀ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.+
13 Àwọn ilé Jerúsálẹ́mù àti ilé àwọn ọba Júdà á sì di aláìmọ́ bí ibí yìí, bíi Tófétì,+ àní títí kan gbogbo ilé tí wọ́n ń rú ẹbọ ní òrùlé rẹ̀ sí gbogbo ọmọ ogun ọ̀run,+ tí wọ́n sì ti ń da ọrẹ ohun mímu sí àwọn ọlọ́run míì.’”+