-
Máàkù 1:32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, tí oòrùn ti wọ̀, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mú gbogbo àwọn tó ní àìlera àti àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu wá sọ́dọ̀ rẹ̀;+
-
-
Ìṣe 5:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ń wá láti àwọn ìlú tó wà ní àyíká Jerúsálẹ́mù, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn àti àwọn tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú wá, gbogbo wọn sì ń rí ìwòsàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.
-