-
Máàkù 5:25-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Obìnrin kan wà tó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀+ fún ọdún méjìlá (12).+ 26 Ó ti jìyà gan-an* lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ oníṣègùn, ó sì ti ná gbogbo ohun tó ní, àmọ́ kàkà kí ara rẹ̀ yá, ṣe ló ń burú sí i. 27 Nígbà tó gbọ́ ìròyìn nípa Jésù, ó gba àárín èrò wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ 28 torí ó ń sọ ṣáá pé: “Tí mo bá fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi á yá.”+ 29 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gbẹ láú, ó sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àìsàn burúkú tó ń ṣe òun ti lọ.
30 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù mọ̀ ọ́n lára pé agbára+ ti jáde lára òun, ó wá yíjú pa dà láàárín èrò náà, ó sì béèrè pé: “Ta ló fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè mi?”+ 31 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé: “O rí i tí èrò ń fún mọ́ ọ, o wá ń béèrè pé, ‘Ta ló fọwọ́ kàn mí?’” 32 Ṣùgbọ́n ó ń wò yí ká kó lè rí ẹni tó fọwọ́ kàn án. 33 Ẹ̀rù ba obìnrin náà, jìnnìjìnnì sì bò ó, torí ó ti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òun, ó wá wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òótọ́ ọ̀rọ̀ náà fún un. 34 Ó dá a lóhùn pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà,+ kí àìsàn burúkú tó ń ṣe ọ́ sì lọ.”+
-
-
Lúùkù 8:43-48Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
43 Obìnrin kan wà tó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀+ fún ọdún méjìlá (12), kò sì tíì rí ìwòsàn lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni.+ 44 Obìnrin náà sún mọ́ ọn láti ẹ̀yìn, ó sì fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì dáwọ́ dúró lójú ẹsẹ̀. 45 Jésù wá sọ pé: “Ta ló fọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn ń sọ pé àwọn kọ́, Pétérù sọ pé: “Olùkọ́, àwọn èrò ń há ọ mọ́, wọ́n sì ń fún mọ́ ọ.”+ 46 Àmọ́ Jésù sọ pé: “Ẹnì kan fọwọ́ kàn mí, torí mo mọ̀ pé agbára+ jáde lára mi.” 47 Nígbà tí obìnrin náà rí i pé òun ò lè fara pa mọ́ mọ́, ó wá, jìnnìjìnnì bò ó, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sọ ohun tó mú kí òun fọwọ́ kàn án níwájú gbogbo èèyàn àti bí ara òun ṣe yá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 48 Àmọ́ ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà.”+
-