-
Máàkù 6:45-52Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
45 Láìjáfara, ó mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọ́n sì ṣáájú rẹ̀ lọ sí etíkun tó wà ní òdìkejì lápá Bẹtisáídà, òun fúnra rẹ̀ sì ní kí àwọn èrò náà máa lọ.+ 46 Lẹ́yìn tó kí wọn pé ó dàbọ̀, ó lọ sórí òkè lọ gbàdúrà.+ 47 Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, ọkọ̀ ojú omi náà ti wà ní àárín òkun, àmọ́ òun nìkan ló wà lórí ilẹ̀.+ 48 Nígbà tó rí i bí wọ́n ṣe ń tiraka láti tukọ̀, torí atẹ́gùn ń dà wọ́n láàmú, ní nǹkan bí ìṣọ́ kẹrin òru,* ó wá sápá ọ̀dọ̀ wọn, ó ń rìn lórí òkun; àmọ́ ó fẹ́* gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá. 49 Nígbà tí wọ́n tajú kán rí i tó ń rìn lórí òkun, wọ́n rò pé: “Ìran abàmì ni!” Wọ́n bá kígbe. 50 Torí gbogbo wọn rí i, ọkàn wọn ò balẹ̀. Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ mọ́kàn le! Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.”+ 51 Ó wá wọnú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú wọn, atẹ́gùn náà sì rọlẹ̀. Èyí yà wọ́n lẹ́nu gan-an, 52 torí wọn ò tíì mọ ohun tí búrẹ́dì náà túmọ̀ sí, ọkàn wọn ò sì tíì ní òye.
-
-
Jòhánù 6:16-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí òkun,+ 17 wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì forí lé Kápánáúmù. Ilẹ̀ ti wá ṣú báyìí, Jésù ò sì tíì wá bá wọn.+ 18 Bákan náà, òkun ti ń ru gùdù torí pé ìjì líle kan ń fẹ́.+ 19 Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti tukọ̀ tó nǹkan bíi máìlì mẹ́ta sí mẹ́rin,* wọ́n rí Jésù tó ń rìn lórí òkun, tó sì ń sún mọ́ ọkọ̀ ojú omi náà, ẹ̀rù sì bà wọ́n. 20 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù!”+ 21 Ìgbà yẹn ni wọ́n wá fẹ́ kó wọnú ọkọ̀ ojú omi náà, ọkọ̀ ojú omi náà sì dé ilẹ̀ tí wọ́n forí lé+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
-