5 “Wò ó! Èmi yóò rán wòlíì Èlíjà sí yín+ kí ọjọ́ ńlá Jèhófà tó ń bani lẹ́rù tó dé.+6 Ó sì máa yí ọkàn àwọn bàbá pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ+ àti ọkàn àwọn ọmọ pa dà sọ́dọ̀ àwọn bàbá, kí n má bàa fìyà jẹ ayé, kí n sì pa á run.”
12 Ó sọ fún wọn pé: “Èlíjà máa kọ́kọ́ wá, ó sì máa mú ohun gbogbo pa dà sí bó ṣe yẹ;+ àmọ́ kí wá nìdí tí a fi kọ ọ́ nípa Ọmọ èèyàn pé ó gbọ́dọ̀ jìyà púpọ̀,+ kí wọ́n sì kàn án lábùkù?+
17 Bákan náà, ó máa lọ ṣáájú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí àti agbára Èlíjà,+ kó lè yí ọkàn àwọn bàbá pa dà sí àwọn ọmọ+ àti àwọn aláìgbọràn sí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ ti àwọn olódodo, kó lè ṣètò àwọn èèyàn tí a ti múra sílẹ̀ fún Jèhófà.”*+