-
Máàkù 12:24-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣebí ìdí tí ẹ fi ṣàṣìṣe nìyẹn, torí pé ẹ ò mọ Ìwé Mímọ́, ẹ ò sì mọ agbára Ọlọ́run?+ 25 Torí tí wọ́n bá jíǹde, àwọn ọkùnrin kì í gbéyàwó, a kì í sì í fa àwọn obìnrin fún ọkọ, àmọ́ wọ́n máa dà bí àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run.+ 26 Àmọ́ ní ti àjíǹde àwọn òkú, ṣé ẹ ò tíì kà á nínú ìwé Mósè ni, nínú ìtàn igi ẹlẹ́gùn-ún, pé Ọlọ́run sọ fún un pé: ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’?+ 27 Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, àmọ́ ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn alààyè. Ẹ mà ṣàṣìṣe o.”+
-