-
Mátíù 22:30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 torí nígbà àjíǹde, àwọn ọkùnrin kì í gbéyàwó, a kì í sì í fa àwọn obìnrin fún ọkọ, àmọ́ wọ́n máa dà bí àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run.+
-
-
Lúùkù 20:34-36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Jésù sọ fún wọn pé: “Àwọn ọmọ ètò àwọn nǹkan yìí* máa ń gbéyàwó, a sì máa ń fà wọ́n fún ọkọ, 35 àmọ́ àwọn tí a ti kà yẹ pé kí wọ́n jèrè ètò àwọn nǹkan yẹn àti àjíǹde òkú kì í gbéyàwó, a kì í sì í fà wọ́n fún ọkọ.+ 36 Kódà, wọn ò lè kú mọ́, torí wọ́n dà bí àwọn áńgẹ́lì, ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n ní ti pé wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ àjíǹde.
-