7 Ó yẹ kí ìmọ̀ máa wà ní ètè àlùfáà, ó sì yẹ kí àwọn èèyàn máa wá òfin ní ẹnu rẹ̀,+ torí ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni.
8 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé: “Àmọ́ ẹ̀yin fúnra yín ti yà kúrò ní ọ̀nà. Ẹ ti lo òfin láti mú ọ̀pọ̀ kọsẹ̀.+ Ẹ ti da májẹ̀mú Léfì.+