-
Máàkù 14:55-59Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
55 Àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sàhẹ́ndìrìn ń wá ẹ̀rí tí wọ́n máa fi mú Jésù kí wọ́n lè pa á, àmọ́ wọn ò rí ìkankan.+ 56 Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ń jẹ́rìí èké sí i,+ àmọ́ ẹ̀rí wọn ò bára mu. 57 Bákan náà, àwọn kan ń dìde, wọ́n sì ń jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ń sọ pé: 58 “A gbọ́ tó sọ pé, ‘Màá wó tẹ́ńpìlì yìí tí wọ́n fi ọwọ́ kọ́ palẹ̀, màá sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ òmíràn tí wọn ò fi ọwọ́ kọ́.’”+ 59 Síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n sọ yìí, ẹ̀rí wọn ò bára mu.
-