-
Máàkù 15:6-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Tí wọ́n bá ń ṣe àjọyọ̀, ó máa ń tú ẹlẹ́wọ̀n kan tí wọ́n bá fẹ́ sílẹ̀ fún wọn.+ 7 Ní àkókò yẹn, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bárábà wà nínú ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú àwọn tó dìtẹ̀ sí ìjọba, tí wọ́n sì pààyàn nígbà tí wọ́n ń dìtẹ̀. 8 Torí náà, àwọn èrò wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ohun tí Pílátù máa ń ṣe fún wọn. 9 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ṣé ẹ fẹ́ kí n tú Ọba Àwọn Júù sílẹ̀ fún yín?”+ 10 Torí Pílátù mọ̀ pé àwọn olórí àlùfáà ń ṣe ìlara rẹ̀ ni wọ́n ṣe fà á lé òun lọ́wọ́.+
-
-
Jòhánù 18:39Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
39 Àmọ́, ẹ ní àṣà kan, pé kí n máa tú ẹnì kan sílẹ̀ fún yín nígbà Ìrékọjá.+ Torí náà, ṣé ẹ fẹ́ kí n tú Ọba Àwọn Júù sílẹ̀ fún yín?”
-