-
Mátíù 27:15-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Tí wọ́n bá ń ṣe àjọyọ̀, ó jẹ́ àṣà gómìnà láti tú ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún àwọn èèyàn, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá fẹ́.+ 16 Àkókò yẹn gan-an ni ẹlẹ́wọ̀n burúkú kan tó lókìkí wà ní àhámọ́ wọn, Bárábà lorúkọ rẹ̀. 17 Torí náà, nígbà tí wọ́n kóra jọ, Pílátù sọ fún wọn pé: “Ta lẹ fẹ́ kí n tú sílẹ̀ fún yín, ṣé Bárábà ni àbí Jésù tí wọ́n ń pè ní Kristi?” 18 Torí Pílátù mọ̀ pé wọ́n ń ṣe ìlara rẹ̀ ni wọ́n ṣe fà á lé òun lọ́wọ́.
-
-
Jòhánù 18:39Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
39 Àmọ́, ẹ ní àṣà kan, pé kí n máa tú ẹnì kan sílẹ̀ fún yín nígbà Ìrékọjá.+ Torí náà, ṣé ẹ fẹ́ kí n tú Ọba Àwọn Júù sílẹ̀ fún yín?”
-