22 Wọ́n wá mú un wá sí ibi tí wọ́n ń pè ní Gọ́gọ́tà, tó túmọ̀ sí “Ibi Agbárí.”+ 23 Ibẹ̀ ni wọ́n ti fẹ́ fún un ní wáìnì tí wọ́n fi òjíá sí kí wáìnì náà lè le,+ àmọ́ kò mu ún. 24 Wọ́n kàn án mọ́gi, wọ́n sì ṣẹ́ kèké lé aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ kí wọ́n lè pinnu ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa mú.+