-
Mátíù 27:33-37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 Nígbà tí wọ́n dé ibì kan tí wọ́n ń pè ní Gọ́gọ́tà, ìyẹn Ibi Agbárí,+ 34 wọ́n fún un ní wáìnì tí wọ́n pò mọ́ òróòro* mu;+ àmọ́ nígbà tó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún. 35 Lẹ́yìn tí wọ́n kàn án mọ́gi, wọ́n fi kèké pín aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ 36 wọ́n sì jókòó síbẹ̀, wọ́n ń ṣọ́ ọ. 37 Wọ́n tún gbé àkọlé sókè orí rẹ̀, tí wọ́n kọ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án sí, pé: “Jésù Ọba Àwọn Júù nìyí.”+
-