Mátíù 26:60, 61 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 60 Àmọ́ wọn ò rí ìkankan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹlẹ́rìí èké ló jáde wá.+ Nígbà tó yá, àwọn méjì wá síwájú, 61 wọ́n sọ pé: “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘Mo lè wó tẹ́ńpìlì Ọlọ́run palẹ̀, kí n sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ.’”+ Jòhánù 2:19 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 19 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ wó tẹ́ńpìlì yìí lulẹ̀, màá sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ.”+
60 Àmọ́ wọn ò rí ìkankan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹlẹ́rìí èké ló jáde wá.+ Nígbà tó yá, àwọn méjì wá síwájú, 61 wọ́n sọ pé: “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘Mo lè wó tẹ́ńpìlì Ọlọ́run palẹ̀, kí n sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ.’”+