36 Lẹ́yìn náà, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ wá sí ibi tí wọ́n ń pè ní Gẹ́tísémánì,+ ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ẹ jókòó síbí, mo fẹ́ lọ sí ọ̀hún yẹn lọ gbàdúrà.”+ 37 Ó mú Pétérù àti àwọn ọmọ Sébédè méjèèjì dání, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ní ẹ̀dùn ọkàn, ìdààmú sì bá a gan-an.+