-
Mátíù 13:54-58Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
54 Lẹ́yìn tó dé agbègbè ìlú rẹ̀,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn nínú sínágọ́gù wọn, débi pé ó yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì sọ pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí ọgbọ́n yìí àti àwọn iṣẹ́ agbára yìí?+ 55 Àbí ọmọ káfíńtà kọ́ nìyí?+ Ṣebí Màríà lorúkọ ìyá rẹ̀, Jémíìsì, Jósẹ́fù, Símónì àti Júdásì sì ni àwọn arákùnrin rẹ̀?+ 56 Ṣebí gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀ ló wà pẹ̀lú wa? Ibo ló ti wá rí gbogbo èyí?”+ 57 Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọsẹ̀ nítorí rẹ̀.+ Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé: “Wòlíì máa ń níyì, àmọ́ kì í gbayì ní ìlú rẹ̀ àti ní ilé òun fúnra rẹ̀.”+ 58 Kò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára níbẹ̀ torí pé wọn ò nígbàgbọ́.
-