ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Máàkù 6:1-6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Ó kúrò níbẹ̀, ó sì wá sí agbègbè ìlú rẹ̀,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀ lé e. 2 Nígbà tó di Sábáàtì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni nínú sínágọ́gù, ẹnu ya ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí àwọn nǹkan yìí?+ Kí nìdí tí a fi fún un ní irú ọgbọ́n yìí, tí a sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ agbára yìí?+ 3 Ṣebí káfíńtà yẹn nìyí,+ ọmọ Màríà,+ tó tún jẹ́ arákùnrin Jémíìsì,+ Jósẹ́fù, Júdásì àti Símónì,+ àbí òun kọ́? Àwọn arábìnrin rẹ̀ sì wà níbí pẹ̀lú wa, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọsẹ̀ nítorí rẹ̀. 4 Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé: “Wòlíì máa ń níyì, àmọ́ kì í gbayì ní ìlú rẹ̀, láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àti ní ilé òun fúnra rẹ̀.”+ 5 Torí náà, kò lè ṣe iṣẹ́ agbára kankan níbẹ̀, ó kàn gbé ọwọ́ rẹ̀ lé díẹ̀ lára àwọn aláìsàn, ó sì wò wọ́n sàn. 6 Ó yà á lẹ́nu pé wọn ò nígbàgbọ́. Ó sì lọ yí ká àwọn abúlé náà, ó ń kọ́ni.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́