20 Ọjọ́ kẹta wá jẹ́ ọjọ́ ìbí+ Fáráò, ó sì se àsè fún gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀, ó wá mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde níṣojú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 21 Ó dá olórí agbọ́tí pa dà sí ipò tó wà tẹ́lẹ̀, ó sì ń gbé ife fún Fáráò. 22 Àmọ́, ó gbé olórí alásè kọ́, bí Jósẹ́fù ṣe túmọ̀ àlá wọn fún wọn.+