-
Máàkù 1:43-45Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
43 Ó wá kìlọ̀ fún un gidigidi, ó sì ní kó máa lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, 44 ó sọ fún un pé: “Rí i pé o ò sọ nǹkan kan fún ẹnikẹ́ni, àmọ́ lọ fi ara rẹ han àlùfáà, kí o sì mú àwọn ohun tí Mósè sọ dání láti wẹ̀ ọ́ mọ́,+ kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.”+ 45 Àmọ́ lẹ́yìn tó lọ, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn rẹ̀ káàkiri, ó sì ń tan ọ̀rọ̀ náà kiri débi pé Jésù ò lè wọ ìlú mọ́ kí àwọn èèyàn má mọ̀, àmọ́ ó dúró sẹ́yìn ìlú láwọn ibi tó dá. Síbẹ̀, wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá láti ibi gbogbo.+
-