-
Léfítíkù 14:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Kí àlùfáà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, kó sì yẹ̀ ẹ́ wò. Tí àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ti lọ lára adẹ́tẹ̀ náà, 4 kí àlùfáà pàṣẹ pé kó mú ààyè ẹyẹ méjì tó mọ́ wá, pẹ̀lú igi kédárì, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti ewéko hísópù láti fi wẹ̀ ẹ́ mọ́.+
-
-
Léfítíkù 14:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “Ní ọjọ́ kẹjọ, kó mú ọmọ àgbò méjì tí ara wọn dá ṣáṣá, abo ọ̀dọ́ àgùntàn+ ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, kó mú ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró tó jẹ́ ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* láti fi ṣe ọrẹ ọkà+ àti òróró tó kún òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì kan;*+ 11 kí àlùfáà tó kéde pé ẹni náà ti di mímọ́ mú ẹni tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ náà wá síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, pẹ̀lú àwọn ọrẹ náà.
-