5 Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! ìkùukùu* tó mọ́lẹ̀ yòò ṣíji bò wọ́n, sì wò ó! ohùn kan dún látinú ìkùukùu náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.+ Ẹ fetí sí i.”+
22 Kódà, Mósè sọ pé: ‘Jèhófà* Ọlọ́run yín máa gbé wòlíì kan bí èmi dìde fún yín láàárín àwọn arákùnrin yín.+ Ẹ gbọ́dọ̀ fetí sí ohun tó bá sọ fún yín.+23 Ní tòótọ́, ẹni* tí kò bá fetí sí Wòlíì yẹn ni a ó pa run pátápátá kúrò láàárín àwọn èèyàn.’+