ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 49:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ọ̀pá àṣẹ kò ní kúrò lọ́dọ̀ Júdà,+ ọ̀pá aláṣẹ kò sì ní kúrò láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀ títí Ṣílò* yóò fi dé,+ òun ni àwọn èèyàn yóò máa ṣègbọràn sí.+

  • Nọ́ńbà 24:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Màá rí i, àmọ́ kì í ṣe báyìí;

      Màá wò ó, àmọ́ kò tíì yá.

      Ìràwọ̀ kan+ máa ti ọ̀dọ̀ Jékọ́bù wá,

      Ọ̀pá àṣẹ+ kan sì máa dìde láti Ísírẹ́lì.+

      Ó sì dájú pé ó máa fọ́ iwájú orí Móábù*+ sí wẹ́wẹ́

      Àti agbárí gbogbo àwọn ọmọ ìdàrúdàpọ̀.

  • Lúùkù 7:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Ẹ̀rù ba gbogbo wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo, wọ́n ní: “A ti gbé wòlíì ńlá kan dìde láàárín wa”+ àti pé, “Ọlọ́run ti yíjú sí àwọn èèyàn rẹ̀.”+

  • Jòhánù 1:45
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 45 Fílípì rí Nàtáníẹ́lì,+ ó sì sọ fún un pé: “A ti rí ẹni tí Mósè, nínú Òfin àti àwọn Wòlíì kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: Jésù, ọmọ Jósẹ́fù,+ láti Násárẹ́tì.”

  • Jòhánù 6:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Nígbà tí àwọn èèyàn rí iṣẹ́ àmì tó ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ó dájú pé Wòlíì tí wọ́n ní ó máa wá sí ayé nìyí.”+

  • Ìṣe 3:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Kódà, Mósè sọ pé: ‘Jèhófà* Ọlọ́run yín máa gbé wòlíì kan bí èmi dìde fún yín láàárín àwọn arákùnrin yín.+ Ẹ gbọ́dọ̀ fetí sí ohun tó bá sọ fún yín.+

  • Ìṣe 7:37
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 37 “Mósè yìí ló sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ọlọ́run máa gbé wòlíì kan bí èmi dìde fún yín láàárín àwọn arákùnrin yín.’+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́