8Lẹ́yìn tó sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà, èrò rẹpẹtẹ rọ́ tẹ̀ lé e. 2 Wò ó! adẹ́tẹ̀ kan wá, ó sì forí balẹ̀* fún un, ó sọ pé: “Olúwa, tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.”+
12 Ní àkókò míì, nígbà tó wà nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú náà, wò ó! ọkùnrin kan wà tí ẹ̀tẹ̀ bò! Nígbà tó tajú kán rí Jésù, ó wólẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé: “Olúwa, tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.”+