-
Máàkù 1:40-44Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
40 Bákan náà, adẹ́tẹ̀ kan wá bá a, ó ń bẹ̀ ẹ́, àní lórí ìkúnlẹ̀, ó sọ fún un pé: “Tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.”+ 41 Àánú rẹ̀ wá ṣe é, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó wá sọ fún un pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí o mọ́.”+ 42 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà pòórá lára rẹ̀, ó sì mọ́. 43 Ó wá kìlọ̀ fún un gidigidi, ó sì ní kó máa lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, 44 ó sọ fún un pé: “Rí i pé o ò sọ nǹkan kan fún ẹnikẹ́ni, àmọ́ lọ fi ara rẹ han àlùfáà, kí o sì mú àwọn ohun tí Mósè sọ dání láti wẹ̀ ọ́ mọ́,+ kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.”+
-
-
Lúùkù 5:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ní àkókò míì, nígbà tó wà nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú náà, wò ó! ọkùnrin kan wà tí ẹ̀tẹ̀ bò! Nígbà tó tajú kán rí Jésù, ó wólẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé: “Olúwa, tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.”+ 13 Torí náà, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó ní: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí o mọ́.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà pòórá lára rẹ̀.+ 14 Ó wá pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé kó má sọ fún ẹnikẹ́ni, ó ní: “Àmọ́ lọ, kí o fi ara rẹ han àlùfáà, kí o sì ṣe ọrẹ láti wẹ̀ ọ́ mọ́, bí Mósè ṣe sọ,+ kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.”+
-