26 Kò gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀ láàárín yín;+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ yín,+27 ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.+
35 Torí náà, ó jókòó, ó pe àwọn Méjìlá náà, ó sì sọ fún wọn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́, òun ló gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni ìkẹyìn àti ìránṣẹ́ gbogbo yín.”+
48 ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá gba ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi gba èmi náà; ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí gba Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.+ Torí ẹni tó bá hùwà bí ẹni tó kéré láàárín gbogbo yín ni ẹni tó tóbi.”+