-
Mátíù 20:26-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Kò gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀ láàárín yín;+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ yín,+ 27 ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.+ 28 Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ èèyàn ò ṣe wá ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ kó lè ṣe ìránṣẹ́,+ kó sì fi ẹ̀mí* rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”+
-
-
Máàkù 10:43-45Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
43 Kò gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀ láàárín yín; àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ yín,+ 44 ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú gbogbo yín. 45 Torí Ọmọ èèyàn pàápàá kò wá ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ kó lè ṣe ìránṣẹ́,+ kó sì fi ẹ̀mí* rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”+
-