Sáàmù 103:10-12 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Kò fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa hùwà sí wa,+Kò sì fi ìyà tó yẹ àṣìṣe wa jẹ wá.+ 11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga ju ayé,Bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ṣe ga.+ 12 Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn,Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.+ Mátíù 6:12 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 12 kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, bí àwa náà ṣe dárí ji àwọn tó jẹ wá ní gbèsè.+ Mátíù 6:14 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 14 “Torí tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run náà máa dárí jì yín;+ Éfésù 4:32 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 32 Àmọ́ ẹ jẹ́ onínúure sí ara yín, kí ẹ máa ṣàánú,+ kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà bí Ọlọ́run náà ṣe tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.+ Kólósè 3:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà,+ kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì.+ Bí Jèhófà* ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.+
10 Kò fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa hùwà sí wa,+Kò sì fi ìyà tó yẹ àṣìṣe wa jẹ wá.+ 11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga ju ayé,Bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ṣe ga.+ 12 Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn,Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.+
32 Àmọ́ ẹ jẹ́ onínúure sí ara yín, kí ẹ máa ṣàánú,+ kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà bí Ọlọ́run náà ṣe tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.+
13 Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà,+ kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì.+ Bí Jèhófà* ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.+