Mátíù 3:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Nígbà yẹn, Jòhánù+ Arinibọmi wá, ó ń wàásù+ ní aginjù Jùdíà, Mátíù 3:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 Àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Jùdíà àti gbogbo ìgbèríko tó yí Jọ́dánì ká máa ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀,+ Mátíù 14:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Hẹ́rọ́dù* ti mú Jòhánù, ó dè é, ó sì fi sẹ́wọ̀n torí Hẹrodíà, ìyàwó Fílípì arákùnrin rẹ̀.+ Mátíù 14:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 Àmọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ pa á, ó ń bẹ̀rù àwọn èèyàn, torí pé wòlíì ni wọ́n kà á sí.+ Máàkù 6:20 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 20 Hẹ́rọ́dù bẹ̀rù Jòhánù, ó mọ̀ pé olódodo ni, èèyàn mímọ́ sì ni,+ torí náà, ó ń dáàbò bò ó. Lẹ́yìn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, kò mọ ohun tó máa ṣe rárá, síbẹ̀ tayọ̀tayọ̀ ló máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
20 Hẹ́rọ́dù bẹ̀rù Jòhánù, ó mọ̀ pé olódodo ni, èèyàn mímọ́ sì ni,+ torí náà, ó ń dáàbò bò ó. Lẹ́yìn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, kò mọ ohun tó máa ṣe rárá, síbẹ̀ tayọ̀tayọ̀ ló máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.