-
Mátíù 22:42-45Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
42 “Kí lèrò yín nípa Kristi? Ọmọ ta ni?” Wọ́n sọ fún un pé: “Ọmọ Dáfídì ni.”+ 43 Ó bi wọ́n pé: “Kí wá nìdí tí Dáfídì fi pè é ní Olúwa nípasẹ̀ ìmísí,+ tó sọ pé, 44 ‘Jèhófà* sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi, títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ”’?+ 45 Tí Dáfídì bá pè é ní Olúwa, báwo ló ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”+
-