-
Lúùkù 20:45-47Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
45 Bí gbogbo èèyàn ṣe ń fetí sílẹ̀, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: 46 “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa rìn kiri nínú aṣọ ńlá, tí wọ́n sì fẹ́ràn kí wọ́n máa kí wọn níbi ọjà, wọ́n fẹ́ ìjókòó iwájú* nínú àwọn sínágọ́gù àti ibi tó lọ́lá jù níbi oúnjẹ alẹ́,+ 47 wọ́n ń jẹ ilé* àwọn opó run, wọ́n sì ń gba àdúrà tó gùn láti ṣe ojú ayé.* Ìdájọ́ tó le* gan-an ni àwọn yìí máa gbà.”
-