-
Mátíù 9:3-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Àwọn akọ̀wé òfin kan wá ń sọ fún ara wọn pé: “Ọ̀gbẹ́ni yìí ń sọ̀rọ̀ òdì.” 4 Jésù mọ ohun tí wọ́n ń rò, ó wá sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ro ohun burúkú nínú ọkàn yín?+ 5 Bí àpẹẹrẹ, èwo ló rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ àbí láti sọ pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn’?+ 6 Àmọ́ kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ èèyàn ní àṣẹ láyé láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini—” ó sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sílé rẹ.”+ 7 Ọkùnrin náà bá dìde, ó sì lọ sílé rẹ̀. 8 Nígbà tí àwọn èrò rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹni tó fún èèyàn nírú àṣẹ yìí.
-
-
Lúùkù 5:21-26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó, wọ́n ń sọ pé: “Ta lẹni tó ń sọ̀rọ̀ òdì yìí? Ta ló lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini yàtọ̀ sí Ọlọ́run nìkan?”+ 22 Àmọ́ Jésù fòye mọ ohun tí wọ́n ń rò, ó sì dá wọn lóhùn pé: “Kí lẹ̀ ń rò lọ́kàn yín? 23 Èwo ló rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ àbí láti sọ pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn’? 24 Àmọ́ kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ èèyàn ní àṣẹ ní ayé láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini—” ó sọ fún ọkùnrin tó ní àrùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “Mò ń sọ fún ọ, Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sílé rẹ.”+ 25 Ló bá dìde níwájú wọn, ó gbé ohun tó ti ń dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó ń yin Ọlọ́run lógo. 26 Ẹnu ya gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, wọ́n ń sọ pé: “A ti rí àwọn nǹkan àgbàyanu lónìí!”
-