55 Ní wákàtí yẹn, Jésù sọ fún àwọn èrò náà pé: “Ṣé èmi lẹ wá fi idà àti kùmọ̀ mú bí olè? Ojoojúmọ́ ni mò ń jókòó nínú tẹ́ńpìlì,+ tí mò ń kọ́ni, àmọ́ ẹ ò mú mi.+ 56 Ṣùgbọ́n gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ohun tí àwọn wòlíì kọ sílẹ̀ lè ṣẹ.” Gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá fi í sílẹ̀,+ wọ́n sì sá lọ.+