52 Jésù wá sọ fún àwọn olórí àlùfáà, àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì àti àwọn àgbààgbà tí wọ́n wá a wá síbẹ̀ pé: “Ṣé olè lẹ fẹ́ wá mú ni, tí ẹ fi kó idà àti kùmọ̀ dání?+ 53 Nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nínú tẹ́ńpìlì lójoojúmọ́,+ ẹ ò fọwọ́ kàn mí.+ Àmọ́ wákàtí yín àti ti àṣẹ òkùnkùn nìyí.”+