-
Máàkù 1:23-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Ní àkókò yẹn, ọkùnrin kan wà nínú sínágọ́gù wọn, tí ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú, ó sì kígbe pé: 24 “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù ará Násárẹ́tì?+ Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́ gan-an, Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run ni ọ́!”+ 25 Àmọ́ Jésù bá a wí, ó ní: “Dákẹ́, kí o sì jáde kúrò nínú rẹ̀!” 26 Lẹ́yìn tí ẹ̀mí àìmọ́ náà mú kí gìrì gbé ọkùnrin náà, tó sì pariwo gan-an, ó jáde kúrò nínú rẹ̀. 27 Ẹnu ya gbogbo àwọn èèyàn náà débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ láàárín ara wọn pé: “Kí nìyí? Ẹ̀kọ́ tuntun ni o! Ó ń lo agbára tó ní láti pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i.” 28 Torí náà, ìròyìn rẹ̀ yára tàn káàkiri gbogbo agbègbè Gálílì.
-