21 àní, bí mo ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́, ọkùnrin náà Gébúrẹ́lì,+ ẹni tí mo ti rí nínú ìran tẹ́lẹ̀,+ wá sọ́dọ̀ mi nígbà tí okun ti tán nínú mi pátápátá, nígbà tí àkókò ọrẹ alẹ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó.
26 Nígbà tó pé oṣù mẹ́fà, Ọlọ́run rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì+ sí ìlú kan ní Gálílì tí wọ́n ń pè ní Násárẹ́tì, 27 sí wúńdíá kan+ tó jẹ́ àfẹ́sọ́nà* ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù ní ilé Dáfídì, orúkọ wúńdíá náà ni Màríà.+