-
Léfítíkù 14:2-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Èyí ni òfin tí ẹ ó máa tẹ̀ lé nípa adẹ́tẹ̀, ní ọjọ́ tí àlùfáà máa kéde rẹ̀ pé ó ti di mímọ́, tí wọ́n á sì mú un wá sọ́dọ̀ àlùfáà.+ 3 Kí àlùfáà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, kó sì yẹ̀ ẹ́ wò. Tí àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ti lọ lára adẹ́tẹ̀ náà, 4 kí àlùfáà pàṣẹ pé kó mú ààyè ẹyẹ méjì tó mọ́ wá, pẹ̀lú igi kédárì, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti ewéko hísópù láti fi wẹ̀ ẹ́ mọ́.+
-